Deuteronomy 8:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
kí ìgbéraga má gba ọkàn yín, kí ẹ sì gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti ń ṣe ẹrú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ki ọkàn rẹ wa gbé soke, iwọ a si gbagbé OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbé ga, tí ẹ ó sì gbàgbé OLÚWA Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Éjíbítì wá, nínú oko ẹrú.