Deuteronomy 8:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ẹni tí ó fi mana tí àwọn baba yín kò jẹ rí bọ́ yín ninu aṣálẹ̀, kí ó lè tẹ orí yín ba, kí ó sì dán yín wò láti ṣe yín ní rere níkẹyìn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o fi manna bọ́ ọ li aginjù, ti awọn baba rẹ kò mọ̀ rí; ki o le rẹ̀ ọ silẹ, ki o le dan ọ wò, lati ṣe ọ li ore nigbẹhin rẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó fún yín ní mánà láti jẹ nínú ihà, ohun tí àwọn baba yín kò mọ̀ rí, kí Òun báà le tẹ orí i yín ba kí ó sì lè dán an yín wò, kí ó báà lè dára fún-un yín.