Deuteronomy 8:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn, mò ń kìlọ̀ fun yín dáradára lónìí pé, bí ẹ bá gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ̀ ń sá káàkiri tọ àwọn oriṣa lẹ́yìn, tí ẹ sì ń bọ wọ́n, píparun ni ẹ óo parun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, bi iwọ ba gbagbe OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ si tẹle ọlọrun miran, ti o si nsìn wọn, ti o si mbọ wọn, emi tẹnumọ́ ọ fun nyin pe, rirun li ẹnyin o run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹ bá wá gbàgbé OLÚWA Ọlọ́run yín, tí ẹ sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn, tí ẹ sì sìn wọ́n, tí ẹ sì foríbalẹ̀ fún wọn, Mo kìlọ̀ fún un yín pé rírun ni ẹ ó run.