Deuteronomy 8:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó tẹ orí yín ba, ó jẹ́ kí ebi pa yín, ó fi mana tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí bọ́ yín, kí ẹ lè mọ̀ pé kìí ṣe oúnjẹ nìkan ní o lè mú kí eniyan wà láàyè, àfi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu OLUWA jáde.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si rẹ̀ ọ silẹ, o si fi ebi pa ọ, o si fi manna bọ́ ọ, ti iwọ kò mọ̀, bẹ̃ni awọn baba rẹ kò mọ̀; ki o le mu ọ mọ̀ pe enia kò ti ipa onjẹ nikan wà lãye, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ ti o ti ẹnu OLUWA jade li enia wà lãye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó rẹ̀ yín sílẹ̀ nípa fífi ebi pa yín, Ó sì fi mánà bọ́ ọ yín, èyí tí ẹ kò mọ̀, tí àwọn baba yín kò mọ̀, kí ó báà lè kọ́ ọ yín pé, ènìyàn kò wà láàyè nípa oúnjẹ nìkan, bí kò ṣe ohun gbogbo tí ó jáde láti ẹnu OLÚWA wá.