Deuteronomy 8:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé ilẹ̀ dáradára ni ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín ń mu yín lọ. Ó kún fún ọpọlọpọ adágún omi, ati orísun omi tí ó ń tú jáde ninu àwọn àfonífojì ati lára àwọn òkè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ wá sinu ilẹ rere, ilẹ odò omi, ti orisun ati ti abẹ-ilẹ, ti nrú soke lati afonifoji ati òke jade wa;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Torí pé OLÚWA Ọlọ́run yín ń mú un yín bọ̀ wá sí ilẹ̀ rere ilẹ̀ tí ó kún fún odò àti ibú omi, pẹ̀lú àwọn ìsun tí ń ṣàn jáde láti orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀.