Deuteronomy 9:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ óo la odò Jọdani kọjá sí òdìkejì lónìí, ẹ óo sì gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ. Àwọn ìlú wọn tóbi, tí odi tí wọ́n mọ yí wọn ká sì ga kan ojú ọ̀run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
GBỌ́, Israeli: iwọ o gòke Jordani li oni, lati wọle lọ ìgba awọn orilẹ-ède ti o tobi ti o si lagbara jù ọ lọ, ilu ti o tobi, ti a mọdi rẹ̀ kàn ọrun,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì. Báyìí, ẹ ti gbáradì látí la Jọ́dánì kọjá, láti lọ gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ, tí wọ́n ní àwọn ìlú ńláńlá, tí odi wọn kan ọ̀run.