Deuteronomy 9:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“OLUWA bá sọ fún mi pé, ‘Dìde, sọ̀kalẹ̀ kíákíá, nítorí pé àwọn eniyan rẹ, tí o kó ti Ijipti wá ti dẹ́ṣẹ̀, wọ́n ti yára yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn, wọ́n ti yá ère tí a fi iná yọ́ fún ara wọn.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun mi pe, Dide, sọkalẹ kánkán lati ihin lọ; nitoriti awọn enia rẹ, ti iwọ mú lati ilẹ Egipti jade wá, ti bà ara wọn jẹ́; nwọn yipada kánkán kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun wọn; nwọn ti yá ere didà fun ara wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA sọ fún mi pé, “Sọ̀kalẹ̀ kúrò níhìnín kíákíá, torí pé àwọn ènìyàn rẹ tí o mú jáde láti Éjíbítì ti hùwà ìbàjẹ́. Wọ́n ti yípadà kíá, nínú àṣẹ mi, wọ́n sì ti ṣe ère dídá fún ara wọn.”