Deuteronomy 9:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí inú tí OLUWA ń bí si yín ati inú rẹ̀ tí kò dùn sí yín bà mí lẹ́rù, nítorí ó ti ṣetán láti pa yín run. Ṣugbọn OLUWA tún gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi nígbà náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti emi bẹ̀ru ibinu ati irunu OLUWA si nyin lati pa nyin run. OLUWA si gbọ́ ti emi nigbana pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo bẹ̀rù ìbínú àti ìrunú OLÚWA, nítorí pé inú bí i sí i yín débi wí pé ó fẹ́ pa yín run. Ṣùgbọ́n OLÚWA tún fetí sí mi lẹ́ẹ̀kàn síi.