Deuteronomy 9:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo gbadura sí OLUWA, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun, má ṣe pa àwọn eniyan rẹ run. Ohun ìní rẹ ni wọ́n, àwọn tí o ti fi agbára rẹ rà pada, tí o fi ipá kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si gbadura sọdọ OLUWA wipe, Oluwa ỌLỌRUN, máṣe run awọn enia rẹ ati iní rẹ, ti iwọ ti fi titobi rẹ̀ ràsilẹ, ti iwọ mú lati Egipti jade wá pẹlu ọwọ́ agbara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo gbàdúrà sí OLÚWA wí pé, “OLÚWA Olódùmarè, má ṣe run àwọn ènìyàn rẹ, àní ogún rẹ tí o ti ràpadà, nípa agbára rẹ tí o sì fi agbára ńlá mú wọn jáde láti Éjíbítì wá.