Deuteronomy 9:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kì í ṣe nítorí ìwà òdodo yín, tabi ìdúróṣinṣin ọkàn yín ni ẹ óo fi rí ilẹ̀ náà gbà; ṣugbọn nítorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ni OLUWA Ọlọrun yín fi ń lé wọn jáde fun yín, kí ó lè mú ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu, àwọn baba yín, ṣẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iṣe nitori ododo rẹ, tabi nitori pipé ọkàn rẹ, ni iwọ fi nlọ lati gbà ilẹ wọn: ṣugbọn nitori ìwabuburu awọn orilẹ-ède wọnyi li OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe lé wọn kuro niwaju rẹ, ati ki o le mu ọ̀rọ na ṣẹ ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ, Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kì í se nítorí òdodo yín, tàbí ìdúróṣinṣin ni ẹ ó fí wọ ìlú wọn lọ láti gba ilẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí ni OLÚWA Ọlọ́run yín yóò fi lé wọn jáde kúrò níwájú u yín láti lè mú ohun tí ó búra fún àwọn baba ṣẹ: fún Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù.