Deuteronomy 9:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ ranti, ẹ má sì ṣe gbàgbé, bí ẹ ti mú OLUWA Ọlọrun yín bínú ninu aṣálẹ̀, láti ọjọ́ tí ẹ ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti títí tí ẹ fi dé ibí yìí ni ẹ̀ ń ṣe oríkunkun sí OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ranti, máṣe gbagbé, bi iwọ ti mu OLUWA Ọlọrun rẹ binu li aginjù: lati ọjọ́ na ti iwọ ti jade kuro ni ilẹ Egipti, titi ẹnyin fi dé ihin yi, ẹnyin ti nṣọ̀tẹ si OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ rántí, ẹ má sì ṣe gbàgbé bí ẹ ti mú OLÚWA Ọlọ́run yín bínú ní ihà. Láti ọjọ́ ti ẹ tí kúrò ní Éjíbítì ni ẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí OLÚWA títí tí ẹ fi dé ìhín yìí.