Ecclesiastes 10:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Má bú ọba, kì báà jẹ́ ninu ọkàn rẹ, má sì gbé ọlọ́rọ̀ ṣépè, kì báà jẹ́ ninu yàrá rẹ, nítorí atẹ́gùn lè gbé ọ̀rọ̀ rẹ lọ, tabi kí àwọn ẹyẹ kan lọ ṣòfófó rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Máṣe bu ọba, ki o má ṣe ninu èro rẹ; máṣe bu ọlọrọ̀ ni iyẹwu rẹ; nitoripe ẹiyẹ oju-ọrun yio gbe ohùn na lọ, ohun ti o ni iyẹ-apá yio si sọ ọ̀ran na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ma ṣe bú ọba, kódà nínú èrò rẹ, tàbí kí o ṣépè fún ọlọ́rọ̀ ní ibi ìbùsùn rẹ, nítorí pé ẹyẹ ojú—ọ̀run le è gbé ọ̀rọ̀ rẹ ẹyẹ tí ó sì ní ìyẹ́ apá le è fi ẹjọ́ ohun tí o sọ sùn.