Ecclesiastes 11:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí eniyan ti wù kí ó pẹ́ láyé tó, kí ó máa yọ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, ṣugbọn kí ó ranti pé ọjọ́ tí òun yóo lò ninu ibojì yóo pọ̀ ju èyí tí òun yóo lò láyé lọ. Asán ni ìgbẹ̀yìn gbogbo ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi enia wà li ọ̀pọlọpọ ọdun, ti o si nyọ̀ ninu gbogbo wọn, sibẹ, jẹ ki o ranti ọjọ òkunkun pe nwọn o pọ̀. Ohun gbogbo ti mbọ̀, asan ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdún tí ó le è lò láyé ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùn nítorí wọn ó pọ̀ Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni.