Ecclesiastes 12:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
nígbà tí àwọn tí ń ṣọ́ ilé yóo máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, tí ẹ̀yìn àwọn alágbára yóo tẹ̀, tí àwọn òòlọ̀ yóo dákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí pé wọn kò pọ̀ mọ́, tí àwọn tí ń wo ìta láti ojú fèrèsé yóo máa ríran bàìbàì;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ ti awọn oluṣọ ile yio warìri, ati ti awọn ọkunrin alagbara yio tẹri wọn ba, awọn õlọ̀ yio si dakẹ nitoriti nwọn kò to nkan, ati awọn ti nwode loju ferese yio ṣu òkunkun,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí olùṣọ́ ilé yóò wárìrì tí àwọn ọkùnrin alágbára yóò tẹríba, nígbà tí àwọn tí ó ń lọ̀ dá kẹ́ nítorí pé wọn kò pọ̀, tí àwọn tí ń wo òde láti ojú fèrèsé yóò ṣókùnkùn;