Ecclesiastes 12:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ẹ̀rù ibi gíga yóo máa bani, ìbẹ̀rù yóo sì wà ní ojú ọ̀nà; tí igi alimọndi yóo tanná, tí tata yóo rọra máa wọ́ ẹsẹ̀ lọ, tí ìfẹ́ ọkàn kò ní sí mọ́, nítorí pé ọkunrin ń lọ sí ilé rẹ̀ ayérayé, àwọn eniyan yóo sì máa ṣọ̀fọ̀ kiri láàrin ìgboro;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pẹlu ti nwọn o bẹ̀ru ibi ti o ga, ti iwariri yio si wà li ọ̀na, ati ti igi almondi yio tanna, ti ẹlẹnga yio di ẹrù, ti ifẹ yio si ṣá: nitoriti ọkunrin nlọ si ile rẹ̀ pipẹ, awọn aṣọ̀fọ yio si ma yide kakiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ènìyàn yóò bẹ̀rù ibi gíga àti ti ìfarapa ní ìgboro; nígbà tí igi álímọ́ǹdì yóò tanná àti tí ẹlẹ́ǹgà yóò wọ́ ara rẹ̀ lọ tí ìfẹ́ kò sì ní ru ṣókè mọ́ nígbà náà ni ènìyàn yóò lọ ilé rẹ́ ayérayé tí àwọn aṣọ̀fọ̀ yóò máa rìn kiri ìgboro.