Ecclesiastes 2:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kò sí ohunkohun tí ojú mi fẹ́ rí tí n kò fún un. Kò sí ìgbádùn kan tí n kò fi tẹ́ ara mi lọ́rùn, nítorí mo jẹ ìgbádùn gbogbo ohun tí mo ṣe. Èrè gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi nìyí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ohunkohun ti oju mi fẹ, emi kò pa a mọ́ fun wọn; emi kò si dù aiya mi li ohun ayò kan; nitoriti aiya mi yọ̀ ninu iṣẹ mi gbogbo; eyi si ni ipin mi lati inu gbogbo lãla mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́. N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn. Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi, èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi.