Ecclesiastes 2:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọ́gbọ́n ní ojú lágbárí, ṣugbọn ninu òkùnkùn ni òmùgọ̀ ń rìn. Sibẹ mo rí i pé, nǹkankan náà ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oju ọlọgbọ́n mbẹ li ori rẹ̀; ṣugbọn aṣiwère nrìn li òkunkun: emitikalami si mọ̀ pẹlu pe, iṣe kanna li o nṣe gbogbo wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ojú ọlọ́gbọ́n ń bẹ lágbárí rẹ̀, nígbà tí aṣiwèrè ń rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n mo wá padà mọ̀ wí pé ìpín kan náà ni ó n dúró de ìsọ̀rí àwọn ènìyàn méjèèjì.