Ecclesiastes 2:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé àtọlọ́gbọ́n, àtòmùgọ̀, kò sẹ́ni tíí ranti wọn pẹ́ lọ títí. Nítorí pé ní ọjọ́ iwájú, gbogbo wọn yóo di ẹni ìgbàgbé patapata. Ẹ wo bí ọlọ́gbọ́n ti í kú bí òmùgọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe iranti kò si fun ọlọgbọ́n pẹlu aṣiwère lailai; ki a wò o pe, bi akoko ti o kọja, bẹ̃li ọjọ ti mbọ, a o gbagbe gbogbo rẹ̀. Ọlọgbọ́n ha ṣe nkú bi aṣiwère?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé ọlọgbọ́n ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí i òmùgọ̀, a kì yóò rántí rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́; gbogbo wọn ni yóò di ohun ìgbàgbé ní ọjọ́ tó ń bọ̀ ikú tí ó pa aṣiwèrè náà ni yóò pa ọlọgbọ́n ènìyàn.