Ecclesiastes 2:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo kórìíra làálàá tí mo ti ṣe láyé, nígbà tí mo rí i pé n óo fi í sílẹ̀ fún ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitõtọ mo korira gbogbo lãla mi ti mo ṣe labẹ õrùn: nitoriti emi o fi i silẹ fun enia ti mbọ̀ lẹhin mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo kóòríra gbogbo ohun tí mo ti ṣíṣẹ́ fún ní abẹ́ oòrùn, nítorí pé mo ní láti fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ó wà lẹ́yìn mi ni.