Ecclesiastes 2:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ta ni ó sì mọ̀ bóyá ọlọ́gbọ́n ni yóo jẹ́, tabi òmùgọ̀ eniyan? Sibẹsibẹ òun ni yóo jọ̀gá lórí gbogbo ohun tí mo fi ọgbọ́n mi kó jọ láyé yìí. Asán ni èyí pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tali o si mọ̀ bi ọlọgbọ́n ni yio ṣe tabi aṣiwère? sibẹ on ni yio ṣe olori iṣẹ mi gbogbo ninu eyi ti mo ṣe lãla, ati ninu eyi ti mo fi ara mi hàn li ọlọgbọ́n labẹ õrùn. Asan li eyi pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ta ni ó wá mọ̀ bóyá ọlọgbọ́n ènìyàn ni yóò jẹ́ tàbí òmùgọ̀? Ṣíbẹ̀ yóò ní láti ṣe àkóso lórí gbogbo iṣẹ́ tí mo tí ṣe yìí pẹ̀lú.