Ecclesiastes 2:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé nígbà mìíràn ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹlu ọgbọ́n, ìmọ̀ ati òye yóo fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí kò ṣe làálàá fún wọn. Asán ni èyí pẹlu, nǹkan burúkú sì ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti enia kan mbẹ, iṣẹ ẹniti o wà li ọgbọ́n ati ni ìmọ, ati ni iṣedẽde; sibẹ ẹniti kò ṣe lãla ninu rẹ̀ ni yio fi i silẹ fun ni ipin rẹ̀. Eyi pẹlu asan ni ati ibi nlanla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnra rẹ̀. Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá.