Ecclesiastes 2:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kò sí ohun tí ó dára fún eniyan ju kí ó jẹun kí ó sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lọ. Sibẹ mo rí i pé ọwọ́ Ọlọrun ni èyí tún ti ń wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò si ohun ti o dara fun enia jù ki o jẹ, ki o si mu ati ki o mu ọkàn rẹ̀ jadùn ohun rere ninu lãla rẹ̀. Eyi ni mo ri pẹlu pe, lati ọwọ Ọlọrun wá ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ènìyàn kò le è ṣe ohun kóhun tí ó dára jù pé kí ó jẹ kí ó sì mu, kí ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ rẹ̀. Mo rí wí pé eléyìí pẹ̀lú wá láti ọwọ́ Ọlọ́run.