Ecclesiastes 2:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọlọrun a máa fún ẹni tí ó bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní ọgbọ́n, ìmọ̀, ati inú dídùn; ṣugbọn iṣẹ́ àtikójọ ati àtitòjọ níí fún ẹlẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n lè fún àwọn tí ó bá wu Ọlọrun. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe Ọlọrun fun enia ti o tọ li oju rẹ̀ li ọgbọ́n, ati ìmọ ati ayọ̀: ṣugbọn ẹlẹṣẹ li o fi ìṣẹ́ fun, lati ma kó jọ ati lati ma tò jọ ki on ki o le ma fi fun ẹni rere niwaju Ọlọrun. Eyi pẹlu asan ni ati imulẹmofo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ni ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹlẹ́ṣẹ̀, o fún-un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun-ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí o tẹ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, aṣán ni, ó dàbí ẹni a gbìyànjú àti mú.