Ecclesiastes 2:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo ronú bí mo ti ṣe lè fi waini mú inú ara mi dùn, ṣugbọn tí kò ní pa ọgbọ́n mọ́ mi ninu; mo tún ronú ohun tí mo lè ṣe pẹlu ìwà òmùgọ̀ títí tí n óo fi lè rí ohun tí ó dára fún ọmọ eniyan láti máa ṣe láyé níwọ̀n àkókò díẹ̀ tí Ọlọrun fún wọn láti gbé lórí ilẹ̀ ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo rò ninu aiya mi lati fi ọti-waini mu ara mi le, ṣugbọn emi nfi ọgbọ́n tọ́ aiya mi: on ati fi ọwọ le iwère, titi emi o fi ri ohun ti o dara fun ọmọ enia, ti nwọn iba mã ṣe labẹ ọrun ni iye ọjọ aiye wọn gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀,—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n. Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀.