Ecclesiastes 2:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo kó fadaka ati wúrà jọ fún ara mi; mo gba ìṣúra àwọn ọba ati ti àwọn agbègbè ìjọba mi. Mo ní àwọn akọrin lọkunrin ati lobinrin, mo sì ní ọpọlọpọ obinrin tíí mú inú ọkunrin dùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si kó fadaka ati wura jọ ati iṣura ti ọba ati ti igberiko, mo ni awọn olorin ọkunrin ati olorin obinrin, ati didùn inu ọmọ enia, aya ati obinrin pupọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo kó wúrà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbéríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin. Mo sì ní onírúurú àwọn obìnrin tí ọkan ọkùnrin le e fà sí.