Ecclesiastes 3:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo wí ní ọkàn ara mi pé, Ọlọrun yóo dájọ́ fún olódodo ati fún eniyan burúkú; nítorí ó ti yan àkókò fún ohun gbogbo ati fún iṣẹ́ gbogbo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo wi li aiya mi pe, Ọlọrun yio ṣe idajọ olododo ati enia buburu: nitoripe ìgba kan mbẹ fun ipinnu ati fun iṣẹ gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo rò nínú ọkàn mi, “Ọlọ́run yóò mú ṣẹ sí ìdájọ́ Olótìítọ́ pẹ̀lú ẹlẹ́ṣẹ̀, Nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́, àti àsìkò fún gbogbo ìṣe.”