Ecclesiastes 3:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
nítorí kò sí ìyàtọ̀ láàrin òpin eniyan ati ti ẹranko. Bí eniyan ṣe ń kú, ni ẹranko ṣe ń kú. Èémí kan náà ni wọ́n ń mí; eniyan kò ní anfaani kankan ju ẹranko lọ; nítorí pé asán ni ohun gbogbo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe ohun ti nṣe ọmọ enia nṣe ẹran; ani ohun kanna li o nṣe wọn: bi ekini ti nkú bẹ̃li ekeji nkú; nitõtọ ẹmi kanna ni gbogbo wọn ní, bẹ̃li enia kò li ọlá jù ẹran lọ: nitoripe asan ni gbogbo rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó ní láti jẹ́ ohun ìrántí pé ìpín ènìyàn rí bí i tẹranko ìpín ń dúró dè wọ́n. Bí ọ̀kan ti ń kú náà ni èkejì yóò kú. Àwọn méjèèjì ni irú èémí kan náà, ènìyàn kò ṣàn ju ẹranko lọ, nítorí pé aṣán ni yíyè jẹ́ fún wọn.