Ecclesiastes 3:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, mo rí i pé kò sí ohun tí ó dára, ju pé kí eniyan jẹ ìgbádùn iṣẹ́ rẹ̀ lọ, nítorí ìpín tirẹ̀ ni. Ta ló lè dá eniyan pada sáyé, kí ó wá rí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ó bá ti kú?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina mo woye pe kò si ohun ti o dara jù ki enia ki o ma yọ̀ ni iṣẹ ara rẹ̀; nitori eyini ni ipin rẹ̀: nitoripe tani yio mu u wá ri ohun ti yio wà lẹhin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, ni mo wá ríi wí pé, kò sí ohun tí ó sàn fún ènìyàn ju kí ó gbádùn iṣẹ́rẹ̀, nítorí pé ìpín tirẹ̀ ni èyí. Tàbí ta ni ó le è mú kí ó rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn-in rẹ̀ kò sí!