Ecclesiastes 4:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo tún rí i bí àwọn eniyan tí ń ni ẹlòmíràn lára láyé. Wò ó! Omi ń bọ́ lójú àwọn tí à ń ni lára, Kò sì sí ẹnìkan tí yóo tù wọ́n ninu. Ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára ni agbára kọ̀dí sí, kò sì sí ẹni tí yóo tu àwọn tí à ń ni lára ninu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
BẸ̃NI mo pada, mo si rò inilara gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn; mo si wò omije awọn ti a nnilara, nwọn kò si ni olutunu; ati lọwọ aninilara wọn ni ipá wà; ṣugbọn nwọn kò ni olutunu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì tún wò ó, mo sì ri gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn: mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kò sì ní Olùtùnú kankan, agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára wọn kò sì ní olùtùnú kankan.