Ecclesiastes 4:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn eniyan tí ó jọba lé lórí pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní òǹkà; sibẹ, àwọn ìran tí ó bá dé lẹ́yìn kò ní máa yọ̀ nítorí rẹ̀. Dájúdájú asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò si opin gbogbo awọn enia na, ani fun gbogbo awọn ti on wà ṣiwaju wọn: awọn pẹlu ti mbọ̀ lẹhin kì yio yọ̀ si i. Nitõtọ asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn tí ó wà ní wájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú. Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.