Ecclesiastes 4:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọkunrin kan wà tí kò ní ẹnìkan, kò lọ́mọ, kò lárá, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìyekan, sibẹsibẹ làálàá rẹ̀ kò lópin, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìtẹ́lọ́rùn ninu ọrọ̀ rẹ̀. Kò fijọ́ kan bi ara rẹ̀ léèrè rí pé, “Ta ni mò ń ṣe làálàá yìí fún tí mo sì ń fi ìgbádùn du ara mi?” Asán ni èyí pàápàá ati ìmúlẹ̀mófo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikan ṣoṣo wà, kò si ni ẹnikeji; nitõtọ kò li ọmọ, bẹ̃ni kò li arakunrin: sibẹ kò si opin ninu lãla rẹ̀ gbogbo; bẹ̃li ọrọ̀ kò tẹ oju rẹ̀ lọrun: bẹ̃ni kò si wipe, Nitori tali emi nṣe lãla, ti mo si nfi ire dù ọkàn mi? Eyi pẹlu asan ni ati iṣẹ òṣi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin kan dá wà, kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí wàhálà rẹ̀ kò lópin, ṣíbẹ̀, ọ̀rọ̀ ohun ìní rẹ̀ kò tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó bèèrè pé, “Nítorí ta ni mo ṣe ń ṣe wàhálà” “àti wí pé kí ni ìdí tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?” Eléyìí náà aṣán ni iṣẹ́ ìbànújẹ́ ni.