Ecclesiastes 5:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nǹkankan ń ṣẹlẹ̀, tí ó burú, tí mo ṣàkíyèsí láyé yìí, àwọn eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ fún ìpalára ara wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ibi buburu kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, eyini ni pe, ọrọ̀ ti a pamọ́ fun ifarapa awọn ti o ni i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùn ọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun oní nǹkan.