Ecclesiastes 6:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹni tí Ọlọrun fún ní ọrọ̀, ohun ìní ati iyì, tí ó ní ohun gbogbo tí ó fẹ́; sibẹsibẹ Ọlọrun kò jẹ́ kí ó gbádùn rẹ̀, ṣugbọn àjèjì ni ó ń gbádùn rẹ̀. Asán ni èyí, ìpọ́njú ńlá sì ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti Ọlọrun fi ọrọ̀, ọlà ati ọlá fun, ti kò si si nkan ti o si kù fun ọkàn rẹ̀ ninu ohun gbogbo ti o fẹ, ṣugbọn ti Ọlọrun kò fun u li agbara ati jẹ ninu rẹ̀, ṣugbọn awọn ajeji enia li o njẹ ẹ: asan li eyi, àrun buburu si ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀, ohun ìní àti ọlà kí ó má ba à ṣe aláìní ohun kóhun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́ ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kò fún un ní àǹfàní láti gbádùn wọn, dípò èyí, àlejò ni ó ń gbádùn wọn. Aṣán ni èyí, àrùn búburú gbáà ni.