Ecclesiastes 6:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ẹnìkan bá bí ọgọrun-un ọmọ, tí ó sì gbé ọpọlọpọ ọdún láyé, ṣugbọn tí kò gbádùn àwọn ohun tí ó dára láyé, tí wọn kò sì sin òkú rẹ̀, ọmọ tí a bí lókùú sàn jù ú lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ọkunrin kan bi ọgọrun ọmọ, ti o si wà li ọdun pupọ, tobẹ̃ ti ọjọ ọdun rẹ̀ pọ̀, ti ọkàn rẹ̀ kò si kún fun ohun didara, ati pẹlu ti a kò si sinkú rẹ̀; mo ni, ọmọ iṣẹnu san jù u lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin kan le è ní ọgọ́rún ọmọ kí ó sì wà láàyè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ṣíbẹ̀ kò sí bí ó ti le wà láàyè pẹ́ tó, bí kò bá le è gbádùn ohun-ìní rẹ̀ kí ó sì gba ìsìnkú tí ó tọ́, mo ṣọ wí pé àbíkú ọmọ ṣàn jù ú lọ.