Ecclesiastes 7:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ninu gbogbo ìgbé-ayé asán mi, mo ti rí àwọn nǹkan wọnyi: Mo ti rí olódodo tí ó ṣègbé ninu òdodo rẹ̀, mo sì ti rí eniyan burúkú tí ẹ̀mí rẹ̀ gùn, pẹlu bí ó ti ń ṣe ibi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ohun gbogbo ni mo ri li ọjọ asan mi: olõtọ enia wà ti o ṣegbé ninu ododo rẹ̀, ati enia buburu wà ti ọjọ rẹ̀ pẹ ninu ìwa buburu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí: Ènìyàn olóòtìítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀ ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀.