Ecclesiastes 7:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo tún pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́, láti ṣe ìwádìí, ati láti wá ọgbọ́n, kí n mọ gbogbo nǹkan, ati ibi tí ń bẹ ninu ìwà òmùgọ̀, ati àìlóye tí ó wà ninu ìwà wèrè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo fi aiya mi si i lati mọ̀, on ati wadi, on ati ṣe afẹri ọgbọ́n ati oye, on ati mọ̀ ìwa buburu wère, ani ti wère ati ti isinwin:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mó wá ròó nínú ọkàn mi láti mọ̀, láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́n àti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ àgọ́ ìwà búburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀.