Ecclesiastes 7:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo rí i pé, nǹkankan wà tí ó burú ju ikú lọ: òun ni obinrin oníṣekúṣe. Ọkàn rẹ̀ dàbí tàkúté ati àwọ̀n, tí ọwọ́ rẹ̀ dàbí ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọrun kò ní bọ́ sọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo kó sinu tàkúté rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si ri ohun ti o korò jù ikú lọ, ani obinrin ti aiya rẹ̀ iṣe idẹkun ati àwọn, ati ọwọ rẹ̀ bi ọbára: ẹnikẹni ti inu Ọlọrun dùn si yio bọ lọwọ rẹ̀; ṣugbọn ẹlẹṣẹ li a o ti ọwọ rẹ̀ mu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo rí ohun tí ó korò ju ikú lọ obìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀bìtì, tí ọkàn rẹ̀ jẹ́ tàkúté tí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n, ọkùnrin tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn yóò le è yọ sílẹ̀ ṣùgbọ́n ẹlẹ́ṣẹ̀ kò le è bọ́ nínú tàkúté rẹ̀.