Ecclesiastes 8:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo rí àwọn ẹni ibi tí a sin sí ibojì. Nígbà ayé wọn, wọn a ti máa ṣe wọlé-wọ̀de ní ibi mímọ́, àwọn eniyan a sì máa yìn wọ́n, ní ìlú tí wọn tí ń ṣe ibi. Asán ni èyí pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni mo si ri isinkú enia buburu, ati awọn ti o ṣe otitọ ti o wá ti o si lọ kuro ni ibi mimọ́, a si gbagbe wọn ni ilu na: asan li eyi pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni mo tún rí ìsìnkú òsìkà—àwọn tí wọ́n máa ń wá tí wọ́n sì ń lọ láti ibi mímọ́ kí wọn sì gba ìyìn ní ìlú tàbí tí wọ́n ti ṣe èyí. Eléyìí pẹ̀lú kò ní ìtumọ̀.