Ecclesiastes 8:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ tilẹ̀ ṣe ibi ní ọpọlọpọ ìgbà tí ọjọ́ rẹ̀ sì gùn, sibẹsibẹ mo mọ̀ pé yóo dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ẹlẹṣẹ tilẹ ṣe ibi nigba ọgọrun, ti ọjọ rẹ̀ si gùn, ṣugbọn nitõtọ, emi mọ̀ pe yio dara fun awọn ti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o bẹ̀ru niwaju rẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òsìkà ènìyàn ń ṣe ọgọ́rùn-ún ibi ṣíbẹ̀ tí ó sì wà láàyè fún ìgbà pípẹ́, mo mọ̀ wí pé yóò dára fún ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run.