Ecclesiastes 8:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ohun asán kan tún wà tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé yìí, a rí àwọn olódodo tí wọn ń jẹ ìyà àwọn eniyan burúkú, tí eniyan burúkú sì ń gba èrè olódodo, asán ni èyí pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Asan kan mbẹ ti a nṣe li aiye; niti pe, olõtọ enia wà, awọn ti o nri fun bi iṣẹ buburu; ati pẹlu, enia buburu wà, awọn ti o nri fun bi iṣẹ olododo: mo ni asan li eyi pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohun mìíràn tún wà tí kò ní ìtumọ̀, tí ó ń ṣẹlẹ̀ láyé olódodo tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí òsìkà àti òsìkà tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí olódodo. Mo ṣọ wí pé eléyìí gan-an kò ní ìtumọ̀.