Ecclesiastes 8:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìmọ̀ràn mi ni pé, kí eniyan máa gbádùn, nítorí kò sí ire kan tí ọmọ eniyan tún ń ṣe láyé ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn lọ; nítorí èyí ni yóo máa bá a lọ ní gbogbo ọjọ́ tí Ọlọrun fún un láyé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni mo yìn iré, nitori enia kò ni ohun rere labẹ õrùn jù jijẹ ati mimu, ati ṣiṣe ariya: nitori eyini ni yio ba a duro ninu lãla rẹ̀ li ọjọ aiye rẹ̀, ti Ọlọrun fi fun u labẹ õrùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà mo kan sáárá sí ìgbádùn ayé, nítorí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ní abẹ́ oòrùn ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí inú rẹ̀ sì dùn lọ. Nígbà náà ni ìdùnú yóò báa rìn nínú iṣẹ́ ẹ rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé ti Ọlọ́run tí fi fún un lábẹ́ oòrùn.