Ecclesiastes 8:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
mo wá rí gbogbo iṣẹ́ Ọlọrun pé, kò sí ẹni tí ó lè rí ìdí iṣẹ́ tí ó ń ṣe láyé. Kò sí bí eniyan ti lè ṣe làálàá tó, kò lè rí ìdí rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ń sọ pé àwọn mọ iṣẹ́ OLUWA, sibẹsibẹ wọn kò lè rí ìdí rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni mo wò gbogbo iṣẹ Ọlọrun, pe enia kò le ridi iṣẹ ti a nṣe labẹ õrùn: nitoripe bi enia tilẹ gbiyanju ati wadi rẹ̀, sibẹ kì yio le ri i; ati pẹlupẹlu bi ọlọgbọ́n enia rò lati wadi rẹ̀, sibẹ kì yio lè ridi rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni mo rí gbogbo ohun tí Ọlọ́run tí ṣe, kò sí ẹnìkan tí ó le è mòye ohun tí ó ń lọ lábẹ́ oòrùn. Láì bìkítà gbogbo ìyànjú rẹ̀ láti wá rí jáde, ènìyàn kò le è mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kódà bí ọlọgbọ́n ènìyàn rò wí pé òun mọ̀ ọ́n, kò le è ní òye rẹ̀ ní pàtó.