Ecclesiastes 9:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo nǹkan wọnyi ni mo fi sọ́kàn. Mo yẹ gbogbo rẹ̀ wò, bí ó ti jẹ́ pé ọwọ́ Ọlọrun ni àwọn olódodo, àwọn ọlọ́gbọ́n, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn wà. Bí ti ìfẹ́ ni, bí ti ìkórìíra ni, ẹnìkan kò mọ̀. Asán ni gbogbo ohun tí ó wà níwájú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NITORI nkan yi ni mo rò li aiya mi, ani lati wadi gbogbo eyi pe, olododo, ati ọlọgbọ́n, ati iṣẹ wọn, lọwọ Ọlọrun li o wà: ifẹni ati irira, kò si ẹniti o mọ̀, gbogbo eyi wà niwaju wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni mo wá ronú lórí gbogbo èyí, tí mo sì parí rẹ̀ pé, olòtìítọ́ àti ọlọ́gbọ́n àti ohun tí wọ́n ń ṣe wà ní ọwọ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò sí ènìyàn tí ó mọ̀ bó yá ìfẹ́ tàbí ìríra ni ó ń dúró de òun.