Ecclesiastes 9:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí nǹkankan náà ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn: ati olódodo ati ẹlẹ́ṣẹ̀, ati eniyan rere ati eniyan burúkú, ati ẹni mímọ́, ati ẹni tí kò mọ́, ati ẹni tí ń rúbọ ati ẹni tí kì í rú. Bí eniyan rere ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹlẹ́ṣẹ̀ náà rí. Bákan náà ni ẹni tí ń búra ati ẹni tí ó takété sì ìbúra.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bakanna li ohun gbogbo ri fun gbogbo wọn: ohun kanna li o nṣe si olododo, ati si ẹni buburu; si enia rere, ati si mimọ́ ati si alaimọ́; si ẹniti nrubọ, ati si ẹniti kò rubọ: bi enia rere ti ri, bẹ̃ li ẹ̀lẹṣẹ; ati ẹniti mbura bi ẹniti o bẹ̀ru ibura.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àyànmọ́ kan náà ni gbogbo wọn ń pín—olótìítọ́ àti òsìkà, rere àti ibi, mímọ́ àti àìmọ́, àwọn tí ó ń rúbọ àti àwọn tí kò rúbọ. Bí ó ti wà pẹ̀lú ọkùnrin rere bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà pẹ̀lú ẹlẹ́ṣẹ̀ bí ó ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó ń ṣe ìbúra bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà pẹ̀lú àwọn tí ó ń bẹ̀rù láti ṣe ìbúra.