Ephesians 1:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo sì tún ń gbadura pé kí ó lè là yín lójú ẹ̀mí, kí ẹ lè mọ ìrètí tí ó ní tí ó fi pè yín, kí ẹ sì lè mọ ògo tí ó wà ninu ogún rẹ̀ tí yóo pín fun yín pẹlu àwọn onigbagbọ,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki oju ọkàn nyin le mọlẹ; ki ẹnyin ki o le mọ ohun ti ireti ìpe rẹ̀ jẹ, ati ohun ti ọrọ̀ ogo ini rẹ̀ ninu awọn enia mimọ́ jẹ,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkan yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìreti ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́.