Ephesians 3:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
kí ẹ lè ní agbára, pẹlu gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun, láti mọ bí ìfẹ́ Kristi ti gbòòrò tó, bí ó ti gùn tó, bí ó ti ga tó, ati bí ó ti jìn tó;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o le li agbara lati mọ̀ pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́, kini ìbú, ati gigùn, ati jijìn, ati giga na jẹ,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga náàìfẹ́ Kírísítì jẹ́.