Ephesians 6:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ẹ lè mọ bí nǹkan ti ń lọ sí lọ́dọ̀ mi, ati ohun tí mò ń ṣe, Tukikọsi yóo sọ gbogbo rẹ̀ fun yín. Àyànfẹ́ arakunrin ni, ati iranṣẹ tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ninu iṣẹ́ Oluwa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ki ẹnyin pẹlu ki o le mọ̀ bi nkan ti ri fun mi, bi mo ti nṣe si, Tikiku arakunrin olufẹ ati iranṣẹ olõtọ ninu Oluwa, yio sọ ohun gbogbo di mimọ̀ fun nyin:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè mọ̀ bí nǹkán ti rí fún mí, bí mo tí ń ṣe sí; Tíkíkù, arákùnrin olùfẹ́ àti ìránṣẹ́ olóòótọ́ nínú Olúwa yóò sọ ohun gbogbo dí mímọ̀ fún yín.