Ephesians 6:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀yin ọ̀gá, bákan náà ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹrú yín. Ẹ má máa dẹ́rù bà wọ́n. Ẹ ranti pé ati àwọn, ati ẹ̀yin, ẹ ní Oluwa kan lọ́run, tí kì í ṣe ojuṣaaju.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ẹnyin oluwa, ẹ mã ṣe ohun kanna si wọn, ẹ mã din ibẹru nyin kù; bi ẹnyin ti mọ pe Oluwa ẹnyin tikaranyin si mbẹ li ọrun; kò si si ojuṣãju enia lọdọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti ẹ̀yín ọ̀gá, ẹ máa ṣe ohun kan náà sí wọn, ẹ máa dín ìbẹ̀rù yín kù bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé olúwa ẹ̀yin tìkárayín ń bẹ ní ọ̀run; kò sì sí ojúṣáájú ènìyàn lọ́dọ̀ rẹ̀.