Esther 1:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn nígbà tí àwọn ìwẹ̀fà tí ọba rán jíṣẹ́ fún un, ó kọ̀, kò wá siwaju ọba. Nítorí náà, inú bí ọba gidigidi, inú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ru.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Faṣti ayaba kọ̀ lati wá nipa aṣẹ ọba lati ọwọ awọn ìwẹfa rẹ̀: nitorina ni ọba binu gidigidi, ibinu rẹ̀ si gbiná ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ọba, ayaba Fásítì kọ̀ láti wá. Nígbà náà ni ọba bínú gidgidi, ìbínú náà sì pọ̀ jọjọ.