Esther 1:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba bá fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n ní òye nípa àkókò, (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ọba máa ń ṣe sí gbogbo àwọn tí wọ́n mọ òfin ati ìdájọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si bi awọn ọlọgbọ́n, ti nwọn moye akokò, (nitori bẹ̃ni ìwa ọba ri si gbogbo awọn ti o mọ̀ ofin ati idajọ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ní ìgbà gbogbo, ọba máa ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ní ìmọ̀ òfin àti ìdájọ́, ó sọ ọ́ fún àwọn amòye tí wọ́n mòye àkókò,